1
Lefitiku 26:12
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Èmi yóò wà pẹ̀lú yín: Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín: Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Lefitiku 26:12
2
Lefitiku 26:4
Èmi yóò rọ̀jò fún yín ní àkókò rẹ̀, kí ilẹ̀ yín le mú èso rẹ̀ jáde bí ó tí yẹ kí àwọn igi eléso yín so èso.
Ṣàwárí Lefitiku 26:4
3
Lefitiku 26:3
“ ‘Bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ẹ̀yin sì ṣọ́ra láti pa òfin mi mọ́.
Ṣàwárí Lefitiku 26:3
4
Lefitiku 26:6
“ ‘Èmi yóò fún yín ní àlàáfíà ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin yóò sì sùn láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Èmi yóò mú kí gbogbo ẹranko búburú kúrò ní ilẹ̀ náà: bẹ́ẹ̀ ni idà kì yóò la ilẹ̀ yín já.
Ṣàwárí Lefitiku 26:6
5
Lefitiku 26:9
“ ‘Èmi yóò fi ojúrere wò yín: Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i: Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín.
Ṣàwárí Lefitiku 26:9
6
Lefitiku 26:13
Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti: kí ẹ̀yin má ba à jẹ́ ẹrú fún wọn mọ́. Mo sì já ìdè àjàgà yín: mo sì mú kí ẹ̀yin máa rìn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbé lórí sókè.
Ṣàwárí Lefitiku 26:13
7
Lefitiku 26:11
Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárín yín. Èmi kò sì ní kórìíra yín.
Ṣàwárí Lefitiku 26:11
8
Lefitiku 26:1
“ ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mọ ère òrìṣà, tàbí kí ẹ̀yin gbe ère kalẹ̀ tàbí kí ẹ̀yin gbẹ́ ère òkúta: kí ẹ̀yin má sì gbẹ́ òkúta tí ẹ̀yin yóò gbé kalẹ̀ láti sìn. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín.
Ṣàwárí Lefitiku 26:1
9
Lefitiku 26:10
Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde: kí ẹ̀yin lè rí ààyè kó tuntun sí.
Ṣàwárí Lefitiku 26:10
10
Lefitiku 26:8
Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa ṣẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn: Àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá: Àwọn ọ̀tá yín yóò tipa idà kú níwájú yín.
Ṣàwárí Lefitiku 26:8
11
Lefitiku 26:5
Èrè oko yín yóò pọ̀ dé bi pé ẹ ó máa pa ọkà títí di àsìkò ìkórè igi eléso, ẹ̀yin yóò sì máa gbé ní ilẹ̀ yín láìléwu.
Ṣàwárí Lefitiku 26:5
12
Lefitiku 26:7
Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀tá yín: wọn yóò sì tipa idà kú.
Ṣàwárí Lefitiku 26:7
13
Lefitiku 26:2
“ ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́ kí ẹ̀yin sì bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi: Èmi ni OLúWA.
Ṣàwárí Lefitiku 26:2
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò