1
Joṣua 6:2
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Nígbà náà ni OLúWA wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo ti fi Jeriko lé ọ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọba rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Joṣua 6:2
2
Joṣua 6:5
Nígbà tí ẹ bá gbọ́ ohùn fèrè náà, kí àwọn ènìyàn hó yèè ní igbe ńlá, nígbà náà ni odi ìlú náà yóò sì wó lulẹ̀, àwọn ènìyàn yóò sì lọ sí òkè, olúkúlùkù yóò sì wọ inú rẹ̀ lọ tààrà.”
Ṣàwárí Joṣua 6:5
3
Joṣua 6:3
Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan pẹ̀lú gbogbo àwọn jagunjagun. Ẹ ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.
Ṣàwárí Joṣua 6:3
4
Joṣua 6:4
Jẹ́ kí àwọn àlùfáà méje gbé fèrè ìwo àgbò ní iwájú àpótí ẹ̀rí. Ní ọjọ́ keje, Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, pẹ̀lú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè.
Ṣàwárí Joṣua 6:4
5
Joṣua 6:1
Wàyí o, a ti há Jeriko mọ́lé gágá nítorí àwọn ọmọ Israẹli, ẹnikẹ́ni kò jáde, ẹnikẹ́ni kò sì wọlé.
Ṣàwárí Joṣua 6:1
6
Joṣua 6:16
Ní ìgbà keje, nígbà tí àwọn àlùfáà fọn fèrè, Joṣua pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ hó! Nítorí pé OLúWA ti fún un yín ní ìlú náà.
Ṣàwárí Joṣua 6:16
7
Joṣua 6:17
Ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀ ni yóò jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ fún OLúWA. Rahabu tí ó jẹ́ panṣágà nìkan àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ ni a ó dá sí; nítorí tí ó pa àwọn ayọ́lẹ̀wò tí á rán mọ́.
Ṣàwárí Joṣua 6:17
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò