1
Joṣua 23:14
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
“Nísinsin yìí èmi ti fẹ́ máa lọ sí ibi tí àwọn àgbà ń rè. Ẹ mọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti àyà yín pé, kò sí ohun kan tí ó kùnà nínú àwọn ìlérí rere gbogbo tí OLúWA Ọlọ́run yín fi fún un yín. Gbogbo ìlérí tó ti ṣe kò sí ọ̀kan tí ó kùnà.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Joṣua 23:14
2
Joṣua 23:11
Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣọ́ra gidigidi láti fẹ́ràn OLúWA Ọlọ́run yín.
Ṣàwárí Joṣua 23:11
3
Joṣua 23:10
Ọ̀kan nínú yín lé ẹgbẹ̀rún ọ̀tá, nítorí tí OLúWA Ọlọ́run yín jà fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí.
Ṣàwárí Joṣua 23:10
4
Joṣua 23:8
Ṣùgbọ́n ẹ di OLúWA Ọlọ́run yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ títí di àkókò yìí.
Ṣàwárí Joṣua 23:8
5
Joṣua 23:6
“Ẹ jẹ́ alágbára gidigidi, kí ẹ sì ṣọ́ra láti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun tí a kọ sí inú Ìwé Ofin Mose, láìyí padà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.
Ṣàwárí Joṣua 23:6
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò