1
Joẹli 2:12
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
“Ǹjẹ́ nítorí náà nísinsin yìí,” ni OLúWA wí, “Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yípadà sí mi, àti pẹ̀lú àwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Joẹli 2:12
2
Joẹli 2:28
“Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́, èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo; àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran.
Ṣàwárí Joẹli 2:28
3
Joẹli 2:13
Ẹ sì fa ọkàn yín ya, kì í sì í ṣe aṣọ yín, ẹ sì yípadà sí OLúWA Ọlọ́run yín, nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú.
Ṣàwárí Joẹli 2:13
4
Joẹli 2:32
Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè orúkọ OLúWA ní a ó gbàlà: nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu ní ìgbàlà yóò gbé wà, bí OLúWA ti wí, àti nínú àwọn ìyókù tí OLúWA yóò pè.
Ṣàwárí Joẹli 2:32
5
Joẹli 2:31
A á sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù OLúWA tó dé.
Ṣàwárí Joẹli 2:31
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò