Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ,
ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLúWA Ọlọ́run rẹ,
ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì
lábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀,
ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’ ”
ni OLúWA wí.
“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni OLúWA wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Sioni.