1
Jeremiah 22:3
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Báyìí ni OLúWA wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Kí ó má ṣe fi agbára àti ìkà lé àlejò, aláìní baba, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Jeremiah 22:3
2
Jeremiah 22:15-16
“Ìwọ ó ha jẹ ọba kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari? Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu? Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo, nítorí náà ó dára fún un. Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní, ohun gbogbo sì dára fún un. Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?” ni OLúWA wí.
Ṣàwárí Jeremiah 22:15-16
3
Jeremiah 22:13
“Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo, àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn.
Ṣàwárí Jeremiah 22:13
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò