1
Isaiah 11:2-3
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀mí OLúWA yóò sì bà lé e ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù OLúWA Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù OLúWA.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Isaiah 11:2-3
2
Isaiah 11:1
Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese, láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso.
Ṣàwárí Isaiah 11:1
3
Isaiah 11:4
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé. Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.
Ṣàwárí Isaiah 11:4
4
Isaiah 11:5
Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀ àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.
Ṣàwárí Isaiah 11:5
5
Isaiah 11:9
Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ OLúWA gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.
Ṣàwárí Isaiah 11:9
6
Isaiah 11:6
Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé, ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́ ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀ ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.
Ṣàwárí Isaiah 11:6
7
Isaiah 11:10
Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.
Ṣàwárí Isaiah 11:10
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò