1
Esekiẹli 18:32
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Nítorí pé inú mi kò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni ni OLúWA Olódùmarè wí. Nítorí náà, ẹ yípadà kí ẹ sì yè!
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Esekiẹli 18:32
2
Esekiẹli 18:20
Ọkàn tí ó bá ṣẹ̀ ní yóò kú. Ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni baba náà kò ní ru ẹ̀bi ọmọ rẹ̀. Ìwà rere ènìyàn rere yóò wà lórí rẹ̀, ìwà búburú ti ènìyàn búburú náà la ó kà sí i lọ́rùn.
Ṣàwárí Esekiẹli 18:20
3
Esekiẹli 18:31
Ẹ kọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti ẹ ti dá sílẹ̀, kí ẹ sì gba ọkàn àti ẹ̀mí tuntun. Nítorí kí ló fi máa kú, ilé Israẹli?
Ṣàwárí Esekiẹli 18:31
4
Esekiẹli 18:23
Ǹjẹ́ èmi ha ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í? Ní OLúWA Olódùmarè wí pé, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ kí ó sì yè?
Ṣàwárí Esekiẹli 18:23
5
Esekiẹli 18:21
“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó ti dá, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àṣẹ mi mọ́, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, nítòótọ́ ni yóò yè, kò sì ní kú.
Ṣàwárí Esekiẹli 18:21
6
Esekiẹli 18:9
Tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lóòtítọ́ àti lódodo. Ó jẹ́ olódodo, yóò yè nítòótọ́, ní OLúWA Olódùmarè wí.
Ṣàwárí Esekiẹli 18:9
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò