1
Deuteronomi 7:9
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé OLúWA Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olóòtítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Deuteronomi 7:9
2
Deuteronomi 7:6
Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí OLúWA Ọlọ́run yín, OLúWA Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrín gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀: ohun ìní iyebíye rẹ̀.
Ṣàwárí Deuteronomi 7:6
3
Deuteronomi 7:8
Ṣùgbọ́n torí Ọlọ́run fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó ṣe fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Farao ọba Ejibiti.
Ṣàwárí Deuteronomi 7:8
4
Deuteronomi 7:7
OLúWA kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ju àwọn ènìyàn yòókù lọ yàn yín, ẹ̀yin sá à lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn.
Ṣàwárí Deuteronomi 7:7
5
Deuteronomi 7:14
A ó bùkún un yín ju gbogbo ènìyàn lọ, kò sí ẹni tí yóò yàgàn nínú ọkùnrin tàbí obìnrin yín, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀kan nínú àwọn ohun ọ̀sìn in yín tí yóò wà láìlọ́mọ.
Ṣàwárí Deuteronomi 7:14
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò