1
2 Ọba 4:2
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Eliṣa dá a lóhùn pé, “Báwo ni èmi ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Sọ fún mi; kí ni ìwọ ní ní ilé rẹ?” “Ìránṣẹ́ rẹ kò ní ohunkóhun níbẹ̀ rárá,” Ó wí pé, “àyàfi òróró kékeré.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí 2 Ọba 4:2
2
2 Ọba 4:1
Ìyàwó ọkùnrin kan láti ara ẹgbẹ́ wòlíì sọkún tọ Eliṣa wá, “Ìránṣẹ́ rẹ ọkọ mi ti kú, ó sì mọ̀ wí pé ó bu ọlá fún OLúWA. Ṣùgbọ́n Nísinsin yìí onígbèsè rẹ̀ ti ń bọ̀ láti wá kó ọmọ ọkùnrin mi gẹ́gẹ́ bí ẹrú rẹ̀.”
Ṣàwárí 2 Ọba 4:1
3
2 Ọba 4:3
Eliṣa wí pé, “Lọ yíká kí o sì béèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn aládùúgbò fún ìkòkò òfìfo. Má ṣe béèrè fún kékeré.
Ṣàwárí 2 Ọba 4:3
4
2 Ọba 4:4
Nígbà náà, lọ sí inú ilé kí o sì pa lẹ́kun dé ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, dà òróró sínú gbogbo ìkòkò, gẹ́gẹ́ bí gbogbo rẹ̀ ti kún, kó o sí apá kan.”
Ṣàwárí 2 Ọba 4:4
5
2 Ọba 4:6
Nígbà tí gbogbo ìkòkò náà kún, ó sọ fún ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ gbé òmíràn fún mi wá.” Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Kò sí ìkòkò tí ó kù mọ́.” Nígbà náà ni òróró kò dà mọ́.
Ṣàwárí 2 Ọba 4:6
6
2 Ọba 4:7
Ó sì lọ ó sì lọ sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì wí pé, “Lọ, ta òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ. Ìwọ àti ọmọ rẹ kí ẹ máa sinmi lórí èyí tí ó kù.”
Ṣàwárí 2 Ọba 4:7
7
2 Ọba 4:5
Ó sì fi sílẹ̀ lẹ́yìn náà ó ti ìlẹ̀kùn ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n gbé ìkòkò wá fún un ó sì ń dà á.
Ṣàwárí 2 Ọba 4:5
8
2 Ọba 4:34
Nígbà náà ó dé orí ibùsùn, ó sùn sórí ọmọ ọkùnrin náà, ẹnu sí ẹnu, ojú sí ojú, ọwọ́ sí ọwọ́. Gẹ́gẹ́ bí ó ti nà ara rẹ̀ lórí rẹ̀, ara ọmọ náà sì gbóná.
Ṣàwárí 2 Ọba 4:34
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò