1
2 Kronika 20:15
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ó sì wí pé, “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ọba Jehoṣafati àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní Juda àti Jerusalẹmu! Èyí ní ohun tí OLúWA sọ wí pé kí a ṣe: ‘Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí fòyà nítorí ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí. Nítorí ogun náà kì í ṣe tiyín, ṣùgbọ́n ti Ọlọ́run ni.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí 2 Kronika 20:15
2
2 Kronika 20:17
Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. Ẹ dúró ní ààyè yín; Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà OLúWA tí yóò fi fún yín, ìwọ Juda àti Jerusalẹmu. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; Ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojúkọ wọ́n ní ọ̀la, OLúWA yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ”
Ṣàwárí 2 Kronika 20:17
3
2 Kronika 20:12
Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn? Nítorí àwa kò ní agbára láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa. Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ.”
Ṣàwárí 2 Kronika 20:12
4
2 Kronika 20:21
Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jehoṣafati yàn wọ́n láti kọrin sí OLúWA àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí iwájú ogun ńlá náà, wí pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA, nítorí àánú rẹ̀ dúró títí láéláé.”
Ṣàwárí 2 Kronika 20:21
5
2 Kronika 20:22
Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, OLúWA rán ogun ẹ̀yìn sí àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu àti òkè Seiri tí ó ń gbógun ti Juda, wọ́n sì kọlù wọ́n.
Ṣàwárí 2 Kronika 20:22
6
2 Kronika 20:3
Nípa ìró ìdágìrì, Jehoṣafati pinnu láti wádìí lọ́wọ́ OLúWA, ó sì kéde àwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Juda.
Ṣàwárí 2 Kronika 20:3
7
2 Kronika 20:9
‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sọkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’
Ṣàwárí 2 Kronika 20:9
8
2 Kronika 20:16
Ní ọ̀la, ẹ sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ, wọn yóò gòkè pẹ̀lú, ẹ̀yin yóò sì rí wọn ní ìpẹ̀kun odò náà, níwájú aginjù Jerueli.
Ṣàwárí 2 Kronika 20:16
9
2 Kronika 20:4
Àwọn ènìyàn Juda sì kó ara wọn jọ pọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ OLúWA; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Juda láti wá a.
Ṣàwárí 2 Kronika 20:4
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò