1
1 Kọrinti 15:58
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ si í ní iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, ní ìwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé iṣẹ́ yin kì í ṣe asán nínú Olúwa.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí 1 Kọrinti 15:58
2
1 Kọrinti 15:57
Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jesu Kristi!
Ṣàwárí 1 Kọrinti 15:57
3
1 Kọrinti 15:33
Kí a má tàn yín jẹ́, “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́.”
Ṣàwárí 1 Kọrinti 15:33
4
1 Kọrinti 15:10
Ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mo rí bí mo ti rí: oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí a fi fún mi kò sì jẹ́ asán; ṣùgbọ́n mó ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ jú gbogbo wọn lọ: ṣùgbọ́n kì í ṣe èmi, bí kò ṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi.
Ṣàwárí 1 Kọrinti 15:10
5
1 Kọrinti 15:55-56
“Ikú, oró rẹ dà? Ikú, ìṣẹ́gun rẹ́ dà?” Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀; àti agbára ẹ̀ṣẹ̀ ni òfin
Ṣàwárí 1 Kọrinti 15:55-56
6
1 Kọrinti 15:51-52
Kíyèsi í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín: gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà, Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìde ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà.
Ṣàwárí 1 Kọrinti 15:51-52
7
1 Kọrinti 15:21-22
Nítorí ìgbà tí ó jẹ́ pé nípa ènìyàn ní ikú ti wá, nípa ènìyàn ní àjíǹde òkú sì ti wá pẹ̀lú. Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Adamu, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kristi.
Ṣàwárí 1 Kọrinti 15:21-22
8
1 Kọrinti 15:53
Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé ara àìkú wọ̀.
Ṣàwárí 1 Kọrinti 15:53
9
1 Kọrinti 15:25-26
Nítorí ti òun gbọdọ̀ ti jẹ ọba kí òun to fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ikú ní ọ̀tá ìkẹyìn tí a ó parun
Ṣàwárí 1 Kọrinti 15:25-26
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò