1
1 Kronika 29:11
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Tìrẹ OLúWA ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn àti ọláńlá àti dídán, nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ OLúWA ni ìjọba; a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí 1 Kronika 29:11
2
1 Kronika 29:12
Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ; ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan. Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti láti fi agbára fún ohun gbogbo.
Ṣàwárí 1 Kronika 29:12
3
1 Kronika 29:14
“Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ.
Ṣàwárí 1 Kronika 29:14
4
1 Kronika 29:13
Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ, a sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo.
Ṣàwárí 1 Kronika 29:13
5
1 Kronika 29:10
Dafidi yin OLúWA níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé, “Ìyìn ni fún Ọ, OLúWA, Ọlọ́run baba a wa Israẹli, láé àti láéláé.
Ṣàwárí 1 Kronika 29:10
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò