1
Luk 19:10
Bibeli Mimọ
Nitori Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Luk 19:10
2
Luk 19:38
Wipe, Olubukun li Ọba ti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: alafia li ọrun, ati ogo loke ọrun.
Ṣàwárí Luk 19:38
3
Luk 19:9
Jesu si wi fun u pe, Loni ni igbala wọ̀ ile yi, niwọnbi on pẹlu ti jẹ ọmọ Abrahamu.
Ṣàwárí Luk 19:9
4
Luk 19:5-6
Nigbati Jesu si de ibẹ̀, o gbé oju soke, o si ri i, o si wi fun u pe, Sakeu, yara, ki o si sọkalẹ; nitori emi kò le ṣaiwọ ni ile rẹ loni. O si yara, o sọkalẹ, o si fi ayọ̀ gbà a.
Ṣàwárí Luk 19:5-6
5
Luk 19:8
Sakeu si dide, o si wi fun Oluwa pe, Wo o, Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fifun talakà; bi mo ba si fi ẹ̀sun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin.
Ṣàwárí Luk 19:8
6
Luk 19:39-40
Awọn kan ninu awọn Farisi li awujọ si wi fun u pe, Olukọni ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ wi. O si da wọn lohùn, o wi fun wọn pe, Mo wi fun nyin, Bi awọn wọnyi ba pa ẹnu wọn mọ́, awọn okuta yio kigbe soke.
Ṣàwárí Luk 19:39-40
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò