1
Lef 26:12
Bibeli Mimọ
Emi o si ma rìn lãrin nyin, emi o si ma ṣe Ọlọrun nyin, ẹnyin o si ma ṣe enia mi.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Lef 26:12
2
Lef 26:4
Nigbana li emi o fun nyin li òjo li akokò rẹ̀, ilẹ yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, igi oko yio si ma so eso wọn.
Ṣàwárí Lef 26:4
3
Lef 26:3
Bi ẹnyin ba nrìn ninu ìlana mi, ti ẹ si npa ofin mi mọ́, ti ẹ si nṣe wọn
Ṣàwárí Lef 26:3
4
Lef 26:6
Emi o si fi alafia si ilẹ na, ẹnyin o si dubulẹ, kò si sí ẹniti yio dẹruba nyin: emi o si mu ki ẹranko buburu ki o dasẹ kuro ni ilẹ na, bẹ̃ni idà ki yio là ilẹ nyin já.
Ṣàwárí Lef 26:6
5
Lef 26:9
Nitoriti emi o fi ojurere wò nyin, emi o si mu nyin bisi i, emi o si sọ nyin di pupọ̀, emi o si gbé majẹmu mi kalẹ pẹlu nyin.
Ṣàwárí Lef 26:9
6
Lef 26:13
Emi li OLUWA Ọlọrun nyin ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ki ẹnyin ki o máṣe wà li ẹrú wọn; emi si ti dá ìde àjaga nyin, mo si mu nyin rìn lõrogangan.
Ṣàwárí Lef 26:13
7
Lef 26:11
Emi o si gbé ibugbé mi kalẹ lãrin nyin: ọkàn mi ki yio si korira nyin.
Ṣàwárí Lef 26:11
8
Lef 26:1
ẸNYIN kò gbọdọ yá oriṣa, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ gbé ere tabi ọwọ̀n kan dide naró fun ara nyin, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ gbé ere okuta gbigbẹ kalẹ ni ilẹ nyin, lati tẹriba fun u: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
Ṣàwárí Lef 26:1
9
Lef 26:10
Ẹnyin o si ma jẹ ohun isigbẹ, ẹnyin o si ma kó ohun ẹgbẹ jade nitori ohun titun.
Ṣàwárí Lef 26:10
10
Lef 26:8
Marun ninu nyin yio si lé ọgọrun, ọgọrun ninu nyin yio si lé ẹgbarun: awọn ọtá nyin yio si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin.
Ṣàwárí Lef 26:8
11
Lef 26:5
Ipakà nyin yio si dé ìgba ikore àjara, igba ikore àjara yio si dé ìgba ifunrugbìn: ẹnyin o si ma jẹ onjẹ nyin li ajẹyo, ẹ o si ma gbé ilẹ nyin li ailewu.
Ṣàwárí Lef 26:5
12
Lef 26:7
Ẹnyin o si lé awọn ọtá nyin, nwọn o si ti ipa idà ṣubu niwaju nyin.
Ṣàwárí Lef 26:7
13
Lef 26:2
Ki ẹnyin ki o pa ọjọ́-isimi mi mọ́, ki ẹ si bọ̀wọ fun ibi mimọ́ mi: Emi li OLUWA.
Ṣàwárí Lef 26:2
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò