1
Jer 18:6
Bibeli Mimọ
Ẹnyin ile Israeli, emi kò ha le fi nyin ṣe gẹgẹ bi amọkoko yi ti ṣe, li Oluwa wi: sa wò o, gẹgẹ bi amọ̀ li ọwọ amọkoko, bẹ̃ni ẹnyin wà li ọwọ mi, ile Israeli.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Jer 18:6
2
Jer 18:7-8
Lojukanna ti emi sọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan lati fà a tu, ati lati fà a lulẹ, ati lati pa a run. Bi orilẹ-ède na ti mo ti sọ ọ̀rọ si ba yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀, emi o yi ọkàn mi pada niti ibi ti emi ti rò lati ṣe si wọn.
Ṣàwárí Jer 18:7-8
3
Jer 18:9-10
Ati lojukanna ti emi sọ ọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan, lati tẹ̀ ẹ do ati lati gbìn i. Bi o ba ṣe ibi niwaju mi, ti kò si gbà ohùn mi gbọ́: nigbana ni emi o yi ọkàn mi pada niti rere, eyiti mo wi pe, emi o ṣe fun wọn.
Ṣàwárí Jer 18:9-10
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò