1
Isa 11:2-3
Bibeli Mimọ
Ẹmi Oluwa yio si bà le e, ẹmi ọgbọ́n ati oye, ẹmi igbimọ̀ ati agbara, ẹmi imọ̀ran ati ibẹ̀ru Oluwa. Õrùn-didùn rẹ̀ si wà ni ibẹ̀ru Oluwa, on ki yio si dajọ nipa ìri oju rẹ̀, bẹ̃ni ki yio dajọ nipa gbigbọ́ eti rẹ̀
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Isa 11:2-3
2
Isa 11:1
ẼKÀN kan yio si jade lati inu kùkute Jesse wá, ẹka kan yio si hù jade lati inu gbòngbo rẹ̀
Ṣàwárí Isa 11:1
3
Isa 11:4
Ṣugbọn yio fi ododo ṣe idajọ talakà, yio si fi otitọ ṣe idajọ fun awọn ọlọkàn tutù aiye; on o si fi ọgọ ẹnu rẹ̀ lu aiye, on o si fi ẽmi ète rẹ̀ lu awọn enia buburu pa.
Ṣàwárí Isa 11:4
4
Isa 11:5
Ododo yio si jẹ amure ẹgbẹ́ rẹ̀, ati iṣotitọ amure inu rẹ̀.
Ṣàwárí Isa 11:5
5
Isa 11:9
Nwọn ki yio panilara, bẹ̃ni nwọn ki yio panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi: nitori aiye yio kún fun ìmọ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bò okun.
Ṣàwárí Isa 11:9
6
Isa 11:6
Ikõkò pẹlu yio ma ba ọdọ-agutan gbe pọ̀, kiniun yio si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ malũ ati ọmọ kiniun ati ẹgbọ̀rọ ẹran abọpa yio ma gbe pọ̀; ọmọ kekere yio si ma dà wọn.
Ṣàwárí Isa 11:6
7
Isa 11:10
Ati li ọjọ na kùkute Jesse kan yio wà, ti yio duro fun ọpágun awọn enia; on li awọn keferi yio wá ri: isimi rẹ̀ yio si li ogo.
Ṣàwárí Isa 11:10
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò