1
Oni 2:26
Bibeli Mimọ
Nitoripe Ọlọrun fun enia ti o tọ li oju rẹ̀ li ọgbọ́n, ati ìmọ ati ayọ̀: ṣugbọn ẹlẹṣẹ li o fi ìṣẹ́ fun, lati ma kó jọ ati lati ma tò jọ ki on ki o le ma fi fun ẹni rere niwaju Ọlọrun. Eyi pẹlu asan ni ati imulẹmofo.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Oni 2:26
2
Oni 2:24-25
Kò si ohun ti o dara fun enia jù ki o jẹ, ki o si mu ati ki o mu ọkàn rẹ̀ jadùn ohun rere ninu lãla rẹ̀. Eyi ni mo ri pẹlu pe, lati ọwọ Ọlọrun wá ni. Nitoripe tali o le jẹun, tabi tani pẹlu ti o le mọ̀ adùn jù mi lọ?
Ṣàwárí Oni 2:24-25
3
Oni 2:11
Nigbati mo wò gbogbo iṣẹ ti ọwọ mi ṣe, ati lãla ti mo ṣe lãla lati ṣe: si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo, ko si si ère kan labẹ õrùn.
Ṣàwárí Oni 2:11
4
Oni 2:10
Ohunkohun ti oju mi fẹ, emi kò pa a mọ́ fun wọn; emi kò si dù aiya mi li ohun ayò kan; nitoriti aiya mi yọ̀ ninu iṣẹ mi gbogbo; eyi si ni ipin mi lati inu gbogbo lãla mi.
Ṣàwárí Oni 2:10
5
Oni 2:13
Nigbana ni mo ri pe ọgbọ́n ta wère yọ, to iwọn bi imọlẹ ti ta òkunkun yọ.
Ṣàwárí Oni 2:13
6
Oni 2:14
Oju ọlọgbọ́n mbẹ li ori rẹ̀; ṣugbọn aṣiwère nrìn li òkunkun: emitikalami si mọ̀ pẹlu pe, iṣe kanna li o nṣe gbogbo wọn.
Ṣàwárí Oni 2:14
7
Oni 2:21
Nitoriti enia kan mbẹ, iṣẹ ẹniti o wà li ọgbọ́n ati ni ìmọ, ati ni iṣedẽde; sibẹ ẹniti kò ṣe lãla ninu rẹ̀ ni yio fi i silẹ fun ni ipin rẹ̀. Eyi pẹlu asan ni ati ibi nlanla.
Ṣàwárí Oni 2:21
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò