1
I. A. Ọba 19:12
Bibeli Mimọ
Ati lẹhin isẹlẹ na, iná; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iná na, ati lẹhin iná na, ohùn kẹ́lẹ kekere.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:12
2
I. A. Ọba 19:4
Ṣugbọn on tikararẹ̀ lọ ni irin ọjọ kan si aginju, o si wá, o si joko labẹ igi juniperi kan, o si tọrọ fun ara rẹ̀ ki on ba le kú; o si wipe, O to; nisisiyi, Oluwa, gba ẹmi mi kuro nitori emi kò sàn jù awọn baba mi lọ!
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:4
3
I. A. Ọba 19:11
O si wipe, Jade lọ, ki o si duro lori oke niwaju Oluwa. Si kiyesi i, Oluwa kọja, ìji nla ati lile si fà awọn oke nla ya, o si fọ́ awọn apata tũtu niwaju Oluwa; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iji na: ati lẹhin iji na, isẹlẹ; ṣugbọn Oluwa kò si ninu isẹlẹ na.
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:11
4
I. A. Ọba 19:13
O si ṣe, nigbati Elijah gbọ́, o si fi agbáda rẹ̀ bo oju rẹ̀, o si jade lọ, o duro li ẹnu iho okuta na. Si kiyesi i, ohùn kan tọ̀ ọ wá wipe, Kini iwọ nṣe nihinyi Elijah?
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:13
5
I. A. Ọba 19:9
O si de ibẹ̀, si ibi ihò okuta, o si wọ̀ sibẹ, si kiyesi i, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ nṣe nihinyi, Elijah?
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:9
6
I. A. Ọba 19:8
O si dide, o si jẹ, o mu, o si lọ li agbara onjẹ yi li ogoji ọsan ati ogoji oru si Horebu, oke Ọlọrun.
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:8
7
I. A. Ọba 19:5
Bi o si ti dùbulẹ ti o si sùn labẹ igi juniperi kan, si wò o, angeli fi ọwọ́ tọ́ ọ, o si wi fun u pe, Dide, jẹun.
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:5
8
I. A. Ọba 19:7
Angeli Oluwa si tun pada wá lẹrinkeji, o si fi ọwọ́ tọ́ ọ, o si wipe, Dide, jẹun; nitoriti ọ̀na na jìn fun ọ.
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:7
9
I. A. Ọba 19:10
On si wipe, Ni jijowu emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ: ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù, nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro.
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:10
10
I. A. Ọba 19:6
O si wò, si kiyesi i, àkara ti a din lori ẹyin iná, ati orù-omi lẹba ori rẹ̀: o si jẹ, o si mu, o si tun dùbulẹ.
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:6
11
I. A. Ọba 19:2
Nigbana ni Jesebeli rán onṣẹ kan si Elijah, wipe, Bẹ̃ni ki awọn òriṣa ki o ṣe si mi ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi emi kò ba ṣe ẹmi rẹ dabi ọkan ninu wọn ni iwoyi ọla.
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:2
12
I. A. Ọba 19:18
Ṣugbọn emi ti kù ẹ̃dẹgbarin enia silẹ fun ara mi ni Israeli, gbogbo ẽkun ti kò tii kunlẹ fun Baali, ati gbogbo ẹnu ti kò iti fi ẹnu kò o li ẹnu.
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:18
13
I. A. Ọba 19:19
Bẹ̃ni o pada kuro nibẹ, o si ri Eliṣa, ọmọ Ṣafati o nfi àjaga malu mejila tulẹ niwaju rẹ̀, ati on na pẹlu ikejila: Elijah si kọja tọ̀ ọ lọ, o si da agbáda rẹ̀ bò o.
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:19
14
I. A. Ọba 19:21
O si pada lẹhin rẹ̀, o si mu àjaga malu kan, o si pa wọn, o si fi ohun-elo awọn malu na bọ̀ ẹran wọn, o si fi fun awọn enia, nwọn si jẹ. On si dide, o si tẹle Elijah lẹhin, o si ṣe iranṣẹ fun u.
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:21
15
I. A. Ọba 19:20
O si fi awọn malu silẹ o si sare tọ̀ Elijah lẹhin o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi lọ ifi ẹnu kò baba ati iya mi li ẹnu, nigbana ni emi o tọ̀ ọ lẹhin. O si wi fun u pe, Lọ, pada, nitori kini mo fi ṣe ọ?
Ṣàwárí I. A. Ọba 19:20
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò