1
I. Kro 29:11
Bibeli Mimọ
Tirẹ Oluwa ni titobi, ati agbara, ati ogo, ati iṣẹgun, ati ọlá-nla: nitori ohun gbogbo li ọrun ati li aiye tirẹ ni; ijọba ni tirẹ, Oluwa, a si gbé ọ leke li ori fun ohun gbogbo.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí I. Kro 29:11
2
I. Kro 29:12
Ọrọ̀ pẹlu ati ọlá ọdọ rẹ ni ti iwá, iwọ si jọba lori ohun gbogbo; li ọwọ rẹ ni agbara ati ipá wà; ati li ọwọ rẹ ni sisọ ni di nla wà, ati fifi agbara fun ohun gbogbo.
Ṣàwárí I. Kro 29:12
3
I. Kro 29:14
Ṣugbọn tali emi, ati kili awọn enia mi, ti a fi le ṣe iranlọwọ tinutinu bi iru eyi? nitori ohun gbogbo ọdọ rẹ ni ti wá, ati ninu ohun ọwọ rẹ li awa ti fi fun ọ.
Ṣàwárí I. Kro 29:14
4
I. Kro 29:13
Njẹ nisisiyi, Ọlọrun wa, awa dupẹ lọwọ rẹ, a si yìn orukọ ogo rẹ.
Ṣàwárí I. Kro 29:13
5
I. Kro 29:10
Nitorina Dafidi fi iyìn fun Oluwa li oju gbogbo ijọ: Dafidi si wipe, Olubukún ni Iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli baba wa lai ati lailai!
Ṣàwárí I. Kro 29:10
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò