1
ORIN DAFIDI 55:22
Yoruba Bible
Kó gbogbo ìṣòro rẹ lé OLUWA lọ́wọ́, yóo sì gbé ọ ró; kò ní jẹ́ kí á ṣí olódodo ní ipò pada.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 55:22
2
ORIN DAFIDI 55:17
Mò ń ráhùn tọ̀sán-tòru, mo sì ń kérora; OLUWA óo gbọ́ ohùn mi.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 55:17
3
ORIN DAFIDI 55:23
Ṣugbọn ìwọ, Ọlọrun, o óo sọ àwọn apani ati àwọn alárèékérekè, sinu kòtò ìparun; wọn kò ní lo ìdajì ọjọ́ ayé wọn. Ṣugbọn èmi óo gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 55:23
4
ORIN DAFIDI 55:16
Ṣugbọn èmi ké pe Ọlọrun; OLUWA yóo sì gbà mí.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 55:16
5
ORIN DAFIDI 55:18
Yóo yọ mí láìfarapa, ninu ogun tí mò ń jà, nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí wọ́n dojú kọ mí, tí wọn ń bá mi jà.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 55:18
6
ORIN DAFIDI 55:1
Tẹ́tí sí adura mi, Ọlọrun, má sì fara pamọ́ nígbà tí mo bá ń bẹ̀bẹ̀.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 55:1
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò