1
ORIN DAFIDI 143:10
Yoruba Bible
Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí pé ìwọ ni Ọlọrun mi. Jẹ́ kí ẹ̀mí rere rẹ máa tọ́ mi ní ọ̀nà tí ó tọ́.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 143:10
2
ORIN DAFIDI 143:8
Jẹ́ kí n máa ranti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ láràárọ̀, nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Kọ́ mi ní ọ̀nà tí n óo máa rìn, nítorí pé ìwọ ni mo gbójú sókè sí.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 143:8
3
ORIN DAFIDI 143:9
OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi; ìwọ ni mo sá di.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 143:9
4
ORIN DAFIDI 143:11
Nítorí ti orúkọ rẹ, OLUWA, dá mi sí; ninu òtítọ́ rẹ, yọ mí ninu ìpọ́njú.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 143:11
5
ORIN DAFIDI 143:1
OLUWA, gbọ́ adura mi; fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi! Dá mi lóhùn ninu òtítọ́ ati òdodo rẹ.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 143:1
6
ORIN DAFIDI 143:7
OLUWA, yára dá mi lóhùn! Ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ pin! Má fara pamọ́ fún mi, kí n má baà dàbí àwọn tí ó ti lọ sinu isà òkú.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 143:7
7
ORIN DAFIDI 143:5
Mo ranti ìgbà àtijọ́, mo ṣe àṣàrò lórí gbogbo ohun tí o ti ṣe, mo sì ronú lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 143:5
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò