1
ỌBADAYA 1:17
Yoruba Bible
“Ṣugbọn ní òkè Sioni ni àwọn tí wọ́n bá sá àsálà yóo máa gbé, yóo sì jẹ́ òkè mímọ́; àwọn ọmọ Jakọbu yóo gba ohun ìní wọn pada.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ỌBADAYA 1:17
2
ỌBADAYA 1:15
“Ọjọ́ ìdájọ́ OLUWA fẹ́rẹ̀ dé sórí àwọn orílẹ̀-èdè; a óo san án fún ọ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ohun tí o bá ṣe, yóo pada sí orí ara rẹ.
Ṣàwárí ỌBADAYA 1:15
3
ỌBADAYA 1:3
Ìgbéraga rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ò ń gbé inú pàlàpálá òkúta, tí ibùgbé rẹ wà lórí òkè gíga, tí o sì ń wí ninu ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni ó lè fà mí lulẹ̀?’
Ṣàwárí ỌBADAYA 1:3
4
ỌBADAYA 1:4
Bí o tilẹ̀ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì, tí ó tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ààrin àwọn ìràwọ̀, láti òkè náà ni n óo ti fà ọ́ lulẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Ṣàwárí ỌBADAYA 1:4
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò