1
MAKU 14:36
Yoruba Bible
Ó ní, “Baba, Baba, ohun gbogbo ṣeéṣe fún ọ. Mú kí ife kíkorò yìí kọjá kúrò lórí mi. Ṣugbọn ìfẹ́ tìrẹ ni kí o ṣe, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí MAKU 14:36
2
MAKU 14:38
Gbogbo yín, ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ tún máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò. Ẹ̀mí fẹ́ ṣe é, ṣugbọn ara kò lágbára.”
Ṣàwárí MAKU 14:38
3
MAKU 14:9
Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, a óo máa sọ ohun tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀ níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé.”
Ṣàwárí MAKU 14:9
4
MAKU 14:34
Ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ lè kú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ máa ṣọ́nà.”
Ṣàwárí MAKU 14:34
5
MAKU 14:22
Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó fún wọn. Ó ní, “Ẹ gbà, èyí ni ara mi.”
Ṣàwárí MAKU 14:22
6
MAKU 14:23-24
Ó tún mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá gbé e fún wọn. Gbogbo wọn mu ninu rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ọpọlọpọ eniyan.
Ṣàwárí MAKU 14:23-24
7
MAKU 14:27
Jesu bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan, àwọn aguntan yóo bá fọ́nká,’
Ṣàwárí MAKU 14:27
8
MAKU 14:42
Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ. Ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá ti súnmọ́ tòsí.”
Ṣàwárí MAKU 14:42
9
MAKU 14:30
Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ní alẹ́ yìí kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ náà yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.”
Ṣàwárí MAKU 14:30
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò