1
MATIU 4:4
Yoruba Bible
Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè, bíkòṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun bá sọ.’ ”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí MATIU 4:4
2
MATIU 4:10
Jesu bá dá a lóhùn, ó ní, “Pada kúrò lẹ́yìn mi, Satani. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o máa sìn.’ ”
Ṣàwárí MATIU 4:10
3
MATIU 4:7
Jesu sọ fún un pé, “Ó tún wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ”
Ṣàwárí MATIU 4:7
4
MATIU 4:1-2
Lẹ́yìn náà, Ẹ̀mí gbé Jesu lọ sí aṣálẹ̀ kí Èṣù lè dán an wò. Lẹ́yìn tí ó ti gbààwẹ̀ tọ̀sán-tòru fún ogoji ọjọ́, ebi wá ń pa á.
Ṣàwárí MATIU 4:1-2
5
MATIU 4:19-20
Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, kì í ṣe ẹja ni ẹ óo máa pamọ́, eniyan ni ẹ óo máa fà wá.” Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Ṣàwárí MATIU 4:19-20
6
MATIU 4:17
Láti àkókò yìí ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu pé, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba ọ̀run súnmọ́ ìtòsí.”
Ṣàwárí MATIU 4:17
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò