1
MATIU 16:24
Yoruba Bible
Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí MATIU 16:24
2
MATIU 16:18
Mo sọ fún ọ pé: Peteru ni ọ́, ní orí àpáta yìí ni n óo kọ́ ìjọ mi lé; agbára ikú kò ní lè ká a.
Ṣàwárí MATIU 16:18
3
MATIU 16:19
N óo fún ọ ní kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run. Ohunkohun tí o bá dè ní ayé, ó di dídè ní ọ̀run. Ohunkohun tí o bá sì tú ní ayé, ó di títú ní ọ̀run.”
Ṣàwárí MATIU 16:19
4
MATIU 16:25
Nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, yóo rí i.
Ṣàwárí MATIU 16:25
5
MATIU 16:26
Nítorí anfaani wo ni ó ṣe eniyan, tí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀? Tabi kí ni eniyan lè fi dípò ẹ̀mí rẹ̀?
Ṣàwárí MATIU 16:26
6
MATIU 16:15-16
Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?” Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun Alààyè.”
Ṣàwárí MATIU 16:15-16
7
MATIU 16:17
Jesu sọ fún un pé, “O káre, Simoni, ọmọ Jona, nítorí kì í ṣe eniyan ni ó fi èyí hàn ọ́ bíkòṣe Baba mi tí ń bẹ lọ́run.
Ṣàwárí MATIU 16:17
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò