1
LEFITIKU 26:12
Yoruba Bible
N óo máa rìn láàrin yín, n óo jẹ́ Ọlọrun yín, ẹ óo sì jẹ́ eniyan mi.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí LEFITIKU 26:12
2
LEFITIKU 26:4
n óo mú kí òjò rọ̀ ní àkókò rẹ̀, ilẹ̀ yóo mú ìbísí rẹ̀ wá, àwọn igi inú oko yóo sì máa so èso.
Ṣàwárí LEFITIKU 26:4
3
LEFITIKU 26:3
“Bí ẹ bá ń tẹ̀lé ìlànà mi, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin mi mọ́
Ṣàwárí LEFITIKU 26:3
4
LEFITIKU 26:6
“N óo fun yín ní alaafia ní ilẹ̀ náà, ẹ óo dùbúlẹ̀, kò sí ẹnìkan tí yóo sì dẹ́rùbà yín. N óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, ogun kò sì ní jà ní ilẹ̀ náà.
Ṣàwárí LEFITIKU 26:6
5
LEFITIKU 26:9
N óo fi ojurere wò yín, n óo mú kí ẹ máa bímọlémọ, kí ẹ sì pọ̀ sí i, n óo sì fi ìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu yín.
Ṣàwárí LEFITIKU 26:9
6
LEFITIKU 26:13
Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí ẹ má baà ṣe ẹrú wọn mọ́. Mo ti dá igi ìdè àjàgà yín kí ẹ lè máa rìn lóòró gangan.
Ṣàwárí LEFITIKU 26:13
7
LEFITIKU 26:11
N óo fi ààrin yín ṣe ibùgbé mi, ọkàn mi kò sì ní kórìíra yín.
Ṣàwárí LEFITIKU 26:11
8
LEFITIKU 26:1
“Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe oriṣa-koriṣa kan fún ara yín, tabi kí ẹ gbé ère gbígbẹ́ kalẹ̀, tabi kí ẹ ri ọ̀wọ̀n òkúta gbígbẹ́ mọ́lẹ̀, kí ẹ sì máa bọ wọ́n, ní gbogbo ilẹ̀ yín, nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.
Ṣàwárí LEFITIKU 26:1
9
LEFITIKU 26:10
Ẹ óo jẹ àwọn nǹkan oko tí ẹ kó sí inú abà fún ọjọ́ pípẹ́, ẹ óo sì máa ru ìyókù wọn dànù kí ẹ lè rí ààyè kó tuntun sí.
Ṣàwárí LEFITIKU 26:10
10
LEFITIKU 26:8
Marun-un ninu yín yóo lé ọgọrun-un ọ̀tá sẹ́yìn, ọgọrun-un ninu yín yóo sì lé ẹgbaarun (10,000) àwọn ọ̀tá yín sẹ́yìn, idà ni ẹ óo fi máa pa wọ́n.
Ṣàwárí LEFITIKU 26:8
11
LEFITIKU 26:5
Ẹ óo máa pa ọkà títí tí èso àjàrà yóo fi tó ká, ẹ óo sì máa ká èso àjàrà lọ́wọ́, títí àwọn nǹkan oko yóo fi tó gbìn. Ẹ óo jẹ, ẹ óo yó, ẹ óo sì máa gbé inú ilẹ̀ yín láìléwu.
Ṣàwárí LEFITIKU 26:5
12
LEFITIKU 26:7
Ẹ óo lé àwọn ọ̀tá yín jáde, ẹ óo sì máa fi idà pa wọ́n.
Ṣàwárí LEFITIKU 26:7
13
LEFITIKU 26:2
Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni OLUWA.
Ṣàwárí LEFITIKU 26:2
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò