Reubẹni, ìwọ ni àkọ́bí mi,
agbára mi, ati àkọ́so èso agbára mi,
ìwọ tí o ní ìgbéraga jùlọ,
tí o sì lágbára jùlọ ninu àwọn ọmọ mi.
Ìwọ tí o dàbí ìkún omi tí ń bì síwá sẹ́yìn,
o kò ní jẹ́ olórí, nítorí pé o ti bá obinrin mi lòpọ̀,
o sì ti sọ ibùsùn èmi baba rẹ di aláìmọ́.