Ṣugbọn bí aboyún náà bá kú tabi bí ó bá farapa, kí wọ́n pa ẹni tí ó ṣe é léṣe náà. Bí ẹnìkan bá fọ́ eniyan lójú, kí wọ́n fọ́ ojú tirẹ̀ náà; bí ẹnìkan bá ká eniyan léyín, kí wọ́n ká eyín tirẹ̀ náà, bí ẹnìkan bá gé eniyan lọ́wọ́, kí wọ́n gé ọwọ́ tirẹ̀ náà, bí ẹnìkan bá gé eniyan lẹ́sẹ̀, kí wọ́n gé ẹsẹ̀ tirẹ̀ náà. Bí ẹnìkan bá fi iná jó eniyan, kí wọ́n fi iná jó òun náà, bí ẹnìkan bá ṣá eniyan lọ́gbẹ́, kí wọ́n ṣá òun náà lọ́gbẹ́, bí ẹnìkan bá na eniyan lẹ́gba, kí wọ́n na òun náà lẹ́gba.