1
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:18
Yoruba Bible
Nítorí pé ọpọlọpọ ọgbọ́n a máa mú ọpọlọpọ ìbànújẹ́ wá, ẹni tí ń fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, ó ń fi kún ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ ni.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:18
2
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:9
Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóo máa wà. Ohun tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀ náà ni a óo tún máa ṣe, kò sí ohun titun kan ní ilé ayé.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:9
3
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:8
Gbogbo nǹkan ní ń kó àárẹ̀ bá eniyan, ju bí ẹnu ti lè sọ lọ. Ìran kì í sú ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ kì í kún etí.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:8
4
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:2-3
Asán ninu asán, bí ọ̀jọ̀gbọ́n ti wí, asán ninu asán, gbogbo rẹ̀ asán ni. Èrè kí ni eniyan ń jẹ ninu gbogbo làálàá rẹ̀, tí ó ń ṣe nílé ayé?
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:2-3
5
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:14
Mo ti wo gbogbo nǹkan tí eniyan ń ṣe láyé, wò ó, asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:14
6
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:4
Ìran kan ń kọjá lọ, òmíràn ń dé, ṣugbọn ayé wà títí laelae.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:4
7
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:11
Kò sí ẹni tí ó ranti àwọn nǹkan àtijọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni, kò sì ní sí ẹni tí yóo ranti àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:11
8
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:17
Mo pinnu lọ́kàn mi láti mọ ohun tí ọgbọ́n jẹ́, ati láti mọ ohun tí ìwà wèrè ati ìwà òmùgọ̀ jẹ́. Mo wá wòye pé èyí pàápàá jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 1:17
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò