1
TIMOTI KEJI 2:15
Yoruba Bible
Sa gbogbo ipá rẹ láti ṣe ara rẹ ní ẹni tí ó yege níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí kò ṣe ohun ìtìjú pamọ́, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí TIMOTI KEJI 2:15
2
TIMOTI KEJI 2:22
Yẹra fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́. Máa lépa òdodo ati ìṣòtítọ́, ìfẹ́, ati alaafia, pẹlu àwọn tí ó ń képe Oluwa pẹlu ọkàn mímọ́.
Ṣàwárí TIMOTI KEJI 2:22
3
TIMOTI KEJI 2:24
Iranṣẹ Oluwa kò sì gbọdọ̀ jà. Ṣugbọn ó níláti máa ṣe jẹ́jẹ́ sí gbogbo eniyan, kí ó jẹ́ olùkọ́ni rere, tí ó ní ìfaradà.
Ṣàwárí TIMOTI KEJI 2:24
4
TIMOTI KEJI 2:13
Bí àwa kò bá tilẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, òun ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nígbà gbogbo, nítorí òun kò lè tan ara rẹ̀ jẹ.”
Ṣàwárí TIMOTI KEJI 2:13
5
TIMOTI KEJI 2:25
Kí ó fi ìfarabalẹ̀ bá àwọn tí ó bá lòdì sí i wí, bóyá Ọlọrun lè fún wọn ní ọkàn ìrònúpìwàdà, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ òtítọ́
Ṣàwárí TIMOTI KEJI 2:25
6
TIMOTI KEJI 2:16
Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán ati ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ràn irú ọ̀rọ̀ wọnyi túbọ̀ ń jìnnà sí ẹ̀sìn Ọlọrun ni.
Ṣàwárí TIMOTI KEJI 2:16
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò