1
ÀWỌN ỌBA KEJI 5:1
Yoruba Bible
Naamani, olórí ogun Siria, jẹ́ eniyan pataki ati ọlọ́lá níwájú ọba Siria, nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni OLUWA ṣe fún ilẹ̀ Siria ní ìṣẹ́gun. Ó jẹ́ akọni jagunjagun, ṣugbọn adẹ́tẹ̀ ni.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 5:1
2
ÀWỌN ỌBA KEJI 5:10
Eliṣa rán iranṣẹ kan kí ó sọ fún un pé kí ó lọ wẹ ara rẹ̀ ninu odò Jọdani ní ìgbà meje, yóo sì rí ìwòsàn.
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 5:10
3
ÀWỌN ỌBA KEJI 5:14
Naamani bá lọ sí odò Jọdani, ó wẹ̀ ní ìgbà meje gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti pàṣẹ fún un, ó rí ìwòsàn, ara rẹ̀ sì jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde.
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 5:14
4
ÀWỌN ỌBA KEJI 5:11
Ṣugbọn Naamani fi ibinu kúrò níbẹ̀, ó ní, “Mo rò pé yóo jáde wá, yóo gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, yóo fi ọwọ́ rẹ̀ pa ibẹ̀, yóo sì ṣe àwòtán ẹ̀tẹ̀ náà ni.
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 5:11
5
ÀWỌN ỌBA KEJI 5:13
Àwọn iranṣẹ rẹ̀ bá gbà á níyànjú pé, “Baba, ṣé bí wolii náà bá sọ pé kí o ṣe ohun tí ó le ju èyí lọ, ṣé o kò ní ṣe é? Kí ló dé tí o kò lè wẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, kí o sì rí ìwòsàn gbà?”
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 5:13
6
ÀWỌN ỌBA KEJI 5:3
Ní ọjọ́ kan, ọmọbinrin náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Bí oluwa mi Naamani bá lọ sí ọ̀dọ̀ wolii tí ó wà ní Samaria, yóo rí ìwòsàn gbà.”
Ṣàwárí ÀWỌN ỌBA KEJI 5:3
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò