Ẹ̀yin olùfẹ́ tí ẹ jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì, mo bẹ̀ yín, ẹ jìnnà sí àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tí ó ń bá ọkàn jagun. Kí ìgbé-ayé yín láàrin àwọn abọ̀rìṣà jẹ́ èyí tí ó dára, tí ó fi jẹ́ pé bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ yín ní àìdára, sibẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà rere yín, wọn yóo yin Ọlọrun lógo ní ọjọ́ ìdájọ́.