1
JOHANU KINNI 5:14
Yoruba Bible
Ìgboyà tí a ní níwájú Ọlọrun nìyí, pé bí a bá bèèrè ohunkohun ní ọ̀nà tí ó fẹ́, yóo gbọ́ tiwa.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí JOHANU KINNI 5:14
2
JOHANU KINNI 5:15
Bí a bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohunkohun tí a bá bèèrè, a mọ̀ pé à ń rí gbogbo ohun tí a bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà.
Ṣàwárí JOHANU KINNI 5:15
3
JOHANU KINNI 5:3-4
Fífẹ́ràn Ọlọrun ni pé kí á pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́: àwọn àṣẹ rẹ̀ kò sì wọni lọ́rùn, nítorí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun ti ṣẹgun ayé. Igbagbọ wa ni ìṣẹ́gun lórí ayé.
Ṣàwárí JOHANU KINNI 5:3-4
4
JOHANU KINNI 5:12
Ẹni tí ó bá ní Ọmọ ní ìyè; ẹni tí kò bá ní Ọmọ Ọlọrun kò ní ìyè.
Ṣàwárí JOHANU KINNI 5:12
5
JOHANU KINNI 5:13
Mo kọ èyí si yín, ẹ̀yin tí ẹ gba orúkọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́, kí ẹ lè mọ̀ pé ẹ ní ìyè ainipẹkun.
Ṣàwárí JOHANU KINNI 5:13
6
JOHANU KINNI 5:18
A mọ̀ pé kò sí ọmọ Ọlọrun kan tíí máa gbé inú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí pé Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ń pa á mọ́, Èṣù kò sì ní fọwọ́ kàn án.
Ṣàwárí JOHANU KINNI 5:18
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò