Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Rut 1:17

Rúùtù
4 Awọn ọjọ
Ètò kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí jẹ́ awílé fún ìwé Rúùtù, ó sì ń ṣe àfihàn ìjólótìítọ́, ìwàláàyè, ìràpadà, àti àánú Ọlọ́run. Tí o bá rò pé o ti sọnù, tàbí o wà lẹ́yìn odi tí ò ń yọjú wọlé, ìtàn Rúùtù yóó ru ọ́ sókè, yóó sì gbé ẹ̀mí rẹ ró láti rán ọ létí pé Jésù, Olùràpadà wa tú oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ jade sórí àwọn tí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀.

Rúútù, Ìtàn Ìràpadà
Ọjọ́ Márùn-ún
Àwọn díẹ̀ ni a lè fi taratara f'ojú jọ nípa ìlàkọjá wọn nínú Bíbélì bíi Rúùtù; tálákà, òpó àtọ̀húnrìnwá tí o fi Ọlọ́run ṣíwájú tí o wá ń wò bí Ó ṣe yí ayé òun padà. Bí o bá ń wá kóríyá nínú àyídáyidà rẹ, má sa láì ka ẹ̀kọ́ yìí!

Irin Ń Lọ Irin: Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí® Ìtọ́ni nínú Májẹ̀mú Láéláé
Ojọ́ Márùn-ún
Ǹjẹ́ òun wòye láti “sọ di ọmọ ẹ̀yìn tó n sọ di omo ẹ̀yìn,” láti tẹ̀lé ìlànà Jésù nínú Àṣẹ Ńlá (Mátíù 28:18-20)? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o leè ti ríi pé ó lè nira láti rí ẹni tí a kò bá fi ṣe olùtọ́ni sọ́nà fún ìgbésẹ̀ yí. Àpẹẹrẹ ta ni o leè tẹ̀lé? Báwo ni sí sọ ni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe rí ní ìgbésí ayé ojoojúmọ́? Ẹ jẹ́ kí a wo inú Májẹ̀mú Àtijó láti wo bí àwọn ọkùnrin márùn àti obìnrin ṣe bu omi rin ayé àwọn míràn, Ẹ̀mí-sí-Ẹ̀mí ®.

Rúùtù: Ìtàn Ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run
Ọjọ́ 7
Bóyá ọ̀kan l'ára àwọn ìtàn kúkúrú tí ó wunilori jù lọ, ní ìwé Rúùtù tí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ ti ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run. Iwe Rúùtù jẹ́ ìtàn tí ó yanilẹ́nu bí Ọlọ́run ṣe nlo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn lásán láti ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ Òun ti o jé Ọba Aláṣẹ. Pẹ̀lú àwọn àkàwé tí ó rẹwà ti ìfẹ́ àti ìrúbọ Krístì fún àwọn ènìyàn Rẹ, a fi hàn wá ipele tí Ọlọ́run lọ láti ra àwọn ọmọ Rẹ̀ padà.