← Àwon ètò
Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú O. Daf 16:7

Gbogbo Ǹkan Tí Mo Nílò
Ọjọ́ Mẹ́ta
Ọlọ́run ti lọ ṣáájú wa ó sì ń pa wá mọ́ ní ọwọ́ ẹ̀yìn. Gbogbo ìdojúkọ wa ló ti yanjú. Gbogbo àlàfo ìdojúkọ ló sì ti dí pẹ̀lú. Ìpèníjà kò lè dé bá a lójijì. Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì ọlọ́jọ́-mẹ́ta yìí ma gbà ẹ́ ní ìyànjú nípa òtítọ́ wípé Ọlọ́run ni Olùpèsè ohun tó tọ́, àti èyí tó yẹ, fún ìgbésí ayé rẹ.

Gbígbọ́ lati Ọ̀run: Títẹ́ Etí S'ílẹ̀ Sí Olúwa Nínú Ìgbésí Ayé Ojoojúmọ́
Ọjọ marun
Olúwa wà láàyè, Ó sì ń ṣiṣẹ́ ní óde òní, Ó ń bá olúkúlùkù àwọn ọmọ Rẹ̀ s'ọ̀rọ̀ ní tààràtà. Àmọ́ ní ìgbà míràn, Ó máa ń ṣòro láti rí I àti láti gbọ́ Ọ. Nípa yíyànnàná ìtàn ìrìn àjò ọkùnrin kan láti ní òye ohùn Ọlọ́run ní ìgbèríko Nairobi, ìwọ yíó mọ bí ó ti rí láti gbọ́ àti láti tẹ̀lé E.