Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mat 5:37
![Àwọn Ìlànà Àńtẹ̀ẹ̀lé Fún Ìmójútó Àkókò Láti Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run](/_next/image?url=https%3A%2F%2F%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F11397%2F640x360.jpg&w=1920&q=75)
Àwọn Ìlànà Àńtẹ̀ẹ̀lé Fún Ìmójútó Àkókò Láti Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ọjọ́ mẹ́fà
Ṣé ó t'ojú sú ọ pé kò sí ju wákàtí mẹ́rinlélógún lọ nínú ọjọ́? Gbogbo ǹkan di ìkàyà fún ọ nítorí oye àwọn iṣẹ́-àkànṣe tó yẹ kí o ṣe? Ṣe ó sú ọ pé gbogbo ìgbà ni ó maá ń rẹ̀tí o kò sì ní àkókò tó láti lò nínú Ọrọ̀-Ọlọ́run àti pẹlú àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rẹ? Eléyìí lè jẹ́ ìdojúkọ tí ó wọ́pọ̀ jù l'áyé. Ìròyìn ayọ̀ ibẹ̀ ni wípé Bíbélì fún wa ní àwọn ìlànà tí a lè lò láti ṣ'èkáwọ́ àkókò wa dáadáa. Ètò-ẹ̀kọ́ yìí yíó fẹ àwọn Ìwé-mímọ́ wọ̀nyí l'ójú yíó sì fún ọ ní àwọn ìmọ̀ràn tí ó wúlò fún bí wàá ṣe lo àwọn àsìkò tó kù l'áyé rẹ dáadáa!
![Lilépa Káróòtì](/_next/image?url=https%3A%2F%2F%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F14957%2F640x360.jpg&w=1920&q=75)
Lilépa Káróòtì
Ọjọ́ méje
Gbogbo wá ló ǹ lépa nǹkan kan.O sábà máa ń jẹ́ nǹkan tí kò sí lárọ́wọ́tó bíi—iṣẹ́ tó dára, ilé tó tún dára,ìdílé pípé, àfọwọ́sí àwọn ẹlòmíràn. Àmó ńjẹ́ èyí kì í múni se àárẹ̀? See kò sí ọ̀nà mìíràn tó dára ni? Ṣe ìwádìí nínú ètò Bíbélì titun tí Life.Church, tí ń tè lé onírúurú ìwàásù Pastor Craig Groeschel nípa, lílépa kárọ́ọ̀tì.