Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mat 4:11
Ṣé Mo Lè B'orí Ẹ̀ṣẹ̀ àtí Ìdánwò Nítòótọ́?
Ọjọ marun
Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ léèrè rí pé, "Kílódé tí mo ṣì ńbá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn já ìjàkadì?" Àpóstélì Pọ́ọ́lù pàápàá sọ bẹ́ẹ̀ ní Róòmù 7:15: "Kìí ṣe ohun tí mo fẹ́ ni èmi ńṣe, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìra ni èmi ńṣe." Báwo ni a ṣe lè dá ẹ̀ṣẹ̀ l'ọ́wọ́ kọ́ kí ó má baà p'agi dínà ìgbé-ayé ẹ̀mí wa? Ṣé èyí tilẹ̀ ṣeéṣe? Jẹ́ kí á jíròrò lórí ẹ̀ṣẹ̀, ìdanwò, Èṣù, àti, ìfẹ́ Ọlọ́run.
Gbígbé Ìgbé Ayé Ọ̀tọ̀: Gbígba Ẹni Tí A Jẹ́
Ọjọ́ mẹ́fà
Pẹ̀lú onírúurú ohùn tí ó ńsọ fún wa irú ẹni tí a óò jẹ́, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé à ún jìjàkadì irúfẹ́ ènìyàn tí à ń pe ara wa. Ọlọ́run Kò fẹ́ kí á fi iṣẹ́ òòjọ́, ipò ìgbéyàwó, tàbí àṣìṣe júwe ara wa. Ó ún fẹ́ kí èrò Rẹ̀ jẹ́ àṣẹ tí ó gajù lórí ayé wa. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́fà yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi òye inú gbé oun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tí o jẹ́ kí o bàa lè gba irúfẹ́ ẹnití òun ṣe nínú Krístì.
Wá Àyè Fún Ohun tó Ṣe Kókó: Ìhùwàsí Ẹ̀mí Márùn-ún Fún Àkókò Lẹ́ńtì
Ọjọ́ Méje
Lẹ́ńtì: àkókò ìyẹaraẹniwò àti ìrònúpìwàdà fún ogójì ọjọ́ gbáko. Èròngbà tó dára ni, àmọ́ báwo ní àkókò Lẹ́ńtì ṣe ma ń rí lára? Ní ọjọ́ méje tó ḿbọ̀, ṣe àwárí àwọn ìhùwàsí márùn-ún ti ẹ̀mí tí o lè bẹ̀rẹ̀ ní àkókò àwẹ̀ yí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ fún ìpèsè sílẹ̀ ọkàn rẹ fún ọjọ́ Àìkú ti Àjíǹde—àti lẹ́yìn rẹ̀.