Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Ẹk. Jer 3:22
Ọgbẹ́ Ọkàn Dé: Ìrètí L'ásìkò Ìsinmi
Ọjọ marun
Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, àkókò ìsinmi jẹ́ àkókò ayọ̀ ńlá...ṣùgbón kíni yío ṣẹlẹ̀ nígbàtí àkókò ìsinmi bá sọ adùn rẹ̀ nù tí ó bá sì di àkókò ìpèníjà látàrí ìbànújẹ́ tàbí àdánù ńlà? Ètò ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí yíó ran àwọn tí ó ń la ìbànújẹ́ kọjá láti ṣàwárí ìtùnù àti ìrètí l'ákòkò ìsinmi, àti láti ṣ'àgbékalẹ̀ àkókò ìsinmi tó n'ítumọ̀ làì fi ti ìbànújẹ́ ọkàn ṣe.
Lilépa Àlàáfíà
Ọjọ́ Méje
Ẹgbé̩e̩ Tearfund ńṣe àfẹ́ẹ́rí ìtó̩ni Ọlọ́run nípa bí wọn yóò ṣe jẹ́ abẹnugan ti àlááfíà, ìmúpadà bọ̀ sípò ìbáṣepọ̀ àti àjọṣepọ̀ tí o múná dóko láàrín àwọn ìletò káàkiri àgbáyé. Ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ méje yìí ní àwọn ìlànà ìṣe fún ìmúpadà bọ̀ sípò àjọ́ṣe rẹ àti gbígbàdúrà fún ayé tí a n gbénú rẹ̀ nípa lílo ọrọ̀ ìjìnlẹ̀ tí n bẹ nínú àwọn òwe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láti rànwálọ́wọ́ kí abaà leè ṣe àwárí àlááfíà Ọlọ́run tío jẹ́ òtítọ́.