← Àwon ètò
Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 4:4
Àyànfẹ́ - Níní Òye Obìnrin Nínú Krístì
Ojo meta
Gẹ́gẹ́ bí obìnrin, a sábà máa ń rí i pé a ní láti ṣe onírúurú nǹkan nínú ìgbésí ayé wa. Àmọ́ ní àárín ìgbòkègbodò yìí, ó ṣe pàtàkì láti rántí irú ẹni tá a jẹ́ nínú ọkàn àyà wa: Àwọn Obìnrin Tí Ọlọ́run Yàn, tàbí Obìnrin Nínú Kristi. Àmì yìí ni ìpìlẹ̀ ìgbésí ayé wa, bá a ṣe lè mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn èèyàn sunwọ̀n sí i. Darapọ mọ wa fun ọjọ mẹta to n bọ bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò ìdánimọ̀ yìí ní kíkún sí i!
Bẹ̀rẹ̀ L'ọ́tun
7 ọjọ
Ọdún Tuntun. Ọjọ́ Tuntun. Ọlọ́run ṣ'ẹ̀dá gbogbo ìsípòpadà yìí láti rán wá l'étí pé Òun ni Ọlọ́run Ìbẹ̀rẹ̀ Ohun Tuntun. Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọ́run fí ọ̀rọ̀ dá ayé, Ó lè s'ọ̀rọ̀ sí òkùnkùn ayé rẹ, kí Ó ṣ'ẹ̀dá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun fún ọ. Ṣé o kò sàì f'ẹ́ràn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun! Gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ẹ̀kọ́ yìí! Máa bá wá kálọ!