Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 15:8
Ìdánilójú
Ọjọ́ Mẹ́rin
Olórun fé jé kí o mò pé a tí gbà onlà àti pé ìwo yóò lọ sí òrun! Ìdánilójú rè ń dàgbà sí nípasẹ ìbápàdé pẹ̀lú Olórun àti ṣíṣe àsàrò nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Àwọn ẹsẹ̀ tó tẹ̀lé, nígbà tí o bá há wọn sórí, lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti simi ni ìdánilójú nínú Ọlọ́run ní gbogbo ọjọ́ ayé rè. Jé kí ayé rẹ ní ìyípadà nípa híhá Àwọn Ìwé Mímó sórí! Fún ìlànà ekún rẹ́rẹ́ fún híhá Àwọn Ìwé Mímó sórí, lọ si MemLok.com
Àyànfẹ́ Ni Ọ́
Ọjọ́ Mẹ́rìn
Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ. Ẹnikẹ́ni tí o kò báà jẹ́, ipele tó wù kí o gbé wà ní ìgbésí ayé rẹ, Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ! Nínú oṣù yí, nígbà tí a bá ńṣe àjọyọ̀ ìfẹ́, má gbàgbé pé ìfẹ́ Ọlọ́run sí ọ ju gbogbo ìfẹ́ tó kù lọ. Nínú ẹ̀kọ́ ẹlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí, ri ara rẹ bọ inú ìfẹ́ Ọlọ́run.
Ẹ̀mí Mímọ́: Ǹjẹ́ A Gba Iná Jẹ Àbí A Se Ìdáàbòbò Kí á má baà Gba Iná Jẹ?
Ọjọ́ méje
Agbára àgbàyanu, tó ń jí òkú dìde ḿbẹ nínú rẹ. Ajíhìnrere Reinhard Bonnke ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó nípọn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ àti wípé ó kọ àwọn Kókó Àgbàyanu nípa Agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Méje yìí ma mú ọ ronú nípa Ẹ̀mí Mímọ́ àti wípé ó máa ru ọ́ sókè láti ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ẹ̀mí náà tó ń gbé nínú rẹ.
Ìgbọ́ràn
2 Ọ̀sẹ̀
Jésù fún rara Rẹ̀ sọ wípé ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ràn Rẹ̀ yóò gbọ́ràn sí ẹ̀kọ́-o Rẹ̀. Láì bìkítà ohun tí ó ba ná wa, ìgbọ́ràn wa ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run. Ètò yìí sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìgbọ́ràn: Bí a ṣe lè ṣẹ̀ ìtọ́jú ìṣàrò ìdúróṣinṣin, ipa àánú, bí ìgbọ́ràn ṣe tú wa sílẹ̀ àti bùkún ayé wa, àti diẹ sii.
Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀
Ọjọ́ 21
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà Gbogbo
Ọgbọ̀n ọjọ́
Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.