Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 15:4
Àyànfẹ́ Ni Ọ́
Ọjọ́ Mẹ́rìn
Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ. Ẹnikẹ́ni tí o kò báà jẹ́, ipele tó wù kí o gbé wà ní ìgbésí ayé rẹ, Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ! Nínú oṣù yí, nígbà tí a bá ńṣe àjọyọ̀ ìfẹ́, má gbàgbé pé ìfẹ́ Ọlọ́run sí ọ ju gbogbo ìfẹ́ tó kù lọ. Nínú ẹ̀kọ́ ẹlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí, ri ara rẹ bọ inú ìfẹ́ Ọlọ́run.
Gbogbo ohun wà ni ìparọ́rọ́: Gbígbà Jésù' Simi ni Kérésìmesì Èyí
Ọjọ marun
Ni àsìkò yìí láti wà ni onímùkẹ́ẹ̀kẹ̀, àmó tún n ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ gan. Tẹ̀ lé mi ká lọ fún àkókò díè péré ti ìsimi àti sise ìjosìn tí o máa gbé o ró jákèjádò làálàá àríyá àsìkò náà. Tá gbé karí ìwé Mímú àwọn ewé odò kúrò ní Àwon Orúko Jésù: Bíbò Onífọkànsìn , Ètò kíkà onífọkànsìn ojó márùn-ún yìí yóò ṣamọ̀nà rè láti gbà Jésù’ simi ni Kérésìmesì nípa gbígbà àsìkò láti rántí dáradára Rè, fi áìní rè hàn, máa wá ìdákêjêjê Rè, áti gbékèlé pé olóòótọ́ Ni i.
Ẹ̀mí Mímọ́: Ǹjẹ́ A Gba Iná Jẹ Àbí A Se Ìdáàbòbò Kí á má baà Gba Iná Jẹ?
Ọjọ́ méje
Agbára àgbàyanu, tó ń jí òkú dìde ḿbẹ nínú rẹ. Ajíhìnrere Reinhard Bonnke ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó nípọn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ àti wípé ó kọ àwọn Kókó Àgbàyanu nípa Agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀kọ́ Ọlọ́jọ́ Méje yìí ma mú ọ ronú nípa Ẹ̀mí Mímọ́ àti wípé ó máa ru ọ́ sókè láti ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ẹ̀mí náà tó ń gbé nínú rẹ.
Ìgbọ́ràn
2 Ọ̀sẹ̀
Jésù fún rara Rẹ̀ sọ wípé ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ràn Rẹ̀ yóò gbọ́ràn sí ẹ̀kọ́-o Rẹ̀. Láì bìkítà ohun tí ó ba ná wa, ìgbọ́ràn wa ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run. Ètò yìí sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìgbọ́ràn: Bí a ṣe lè ṣẹ̀ ìtọ́jú ìṣàrò ìdúróṣinṣin, ipa àánú, bí ìgbọ́ràn ṣe tú wa sílẹ̀ àti bùkún ayé wa, àti diẹ sii.
Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà Gbogbo
Ọgbọ̀n ọjọ́
Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.