Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 15:12
Àyànfẹ́ Ni Ọ́
Ọjọ́ Mẹ́rìn
Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ. Ẹnikẹ́ni tí o kò báà jẹ́, ipele tó wù kí o gbé wà ní ìgbésí ayé rẹ, Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ! Nínú oṣù yí, nígbà tí a bá ńṣe àjọyọ̀ ìfẹ́, má gbàgbé pé ìfẹ́ Ọlọ́run sí ọ ju gbogbo ìfẹ́ tó kù lọ. Nínú ẹ̀kọ́ ẹlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí, ri ara rẹ bọ inú ìfẹ́ Ọlọ́run.
Kí nìdí tí Ọlọrun Fẹràn Mi?
Ọjọ marun
Awọn ibeere: Nigba ti o ba de ọdọ Ọlọrun, gbogbo wa ni wọn. Fun awọn aṣa ti a ti ṣe apejuwe, ọkan ninu awọn ibeere ti ara ẹni ti a le rii ara wa ni, "Kini idi ti Ọlọrun fẹràn mi?" Tabi boya ani, "Bawo ni O ṣe le wa?" Ni opin ètò yii, iwọ yoo ṣe alabapin pẹlu gbogbo awọn ọrọ mimọ mimọ--kọọkan ti o sọ otitọ ti ifẹ ti ailopin ti Ọlọrun fun ọ.
Fẹ́ràn bí Jésù
Ojọ́ Métàlá
Báwo ni a ṣe lè kọ́ láti gbé bí Jésù tí a kò bá kọ́kọ́ fẹ́ràn bí Ẹ̀? Máa káa lo pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ àti tọkọtaya Life.Church bí wọn ṣe sọ asòtúnsọ àwọn ìrírí àti àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ tó fi wọn sábẹ́ ìmísì láti gbé àti fẹ́ràn bí Jésù.
Ìgbọ́ràn
2 Ọ̀sẹ̀
Jésù fún rara Rẹ̀ sọ wípé ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ràn Rẹ̀ yóò gbọ́ràn sí ẹ̀kọ́-o Rẹ̀. Láì bìkítà ohun tí ó ba ná wa, ìgbọ́ràn wa ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run. Ètò yìí sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìgbọ́ràn: Bí a ṣe lè ṣẹ̀ ìtọ́jú ìṣàrò ìdúróṣinṣin, ipa àánú, bí ìgbọ́ràn ṣe tú wa sílẹ̀ àti bùkún ayé wa, àti diẹ sii.
Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà Gbogbo
Ọgbọ̀n ọjọ́
Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.