Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 10:10
Ìyípadà Láti Ṣẹ́pá Àwọn Ìdààmú Ọkàn
Ọjọ́ Mẹ́ta
Ti ayé rẹ̀ bá yàtọ̀ sí ètò Ọlọ́run, dandan ni kí o kọjú ìṣòro àti ìdààmú. Ti ẹ̀dùn ọkàn bá borí ẹ, tó bẹ̀rẹ̀ sì ni nípa lórí àlàáfíà rẹ, wàá ri pe o ti tì ra re sínú àhámọ́ tó ṣòro láti jade kuro. O nilo láti wá iwọntunwọnsi ki o si gbẹkẹle Ọlọ́run. Je ki Tony Evans salaye bó o ṣe lè lómìnira ọkàn.
Fífetí sì Ọlọ́run
Ọjọ́ méje
Amy Groeschel ti kọ ètò bíbélì yìí ní ìrètí pé yóò di ìtẹ́wọ́gbà bíi wípé ó wá tààrà láti ọkàn Ọlọ́run olùfẹ́ wa sí ọkàn rẹ. Àdúrà Òun tìkálára ni wípé yóò kó̩ ọ láti yàgò fún ohùn tí ń tako ni àti láti tani jí sí ìfiyè sí ohùn rẹ̀.
Bò Nínú Àjàgà Ìfarawéra Ẹ̀kọ́-Àṣàrò Ọlọ́jọ́ Méje Látọwọ́ Anna Light
Ọjọ́ Méje
Ìwọ́ mọ̀ wípé Ọlọ́rùn pèsè ìgbé ayé ọpọ yantúrú jú èyí tó ń gbé yì lọ, àmọ́ òtítọ́ tó kóro ní wípé ṣíṣe ìfáráwéra fà ọ sẹ́yìn láti lọ sí ipélé tó kan. Nínú ètò kíkà yìí Anna Light hú àwọn ìjìnlẹ̀ òye jáde láti fọ́ àpótí tí ìfáráwéra fi dé àwọ́n àbùdá rẹ, àti ràn ọ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé òmìnira oún ìgbé ayé ọ́pọ yantúrú tí Ọlọ́rùn tí yà sọ́tọ fún ọ
Ìmọ̀lára Mímọ́ - Èsì Látinú Bíbélì sí Ìpèníjà Gbogbo
Ọgbọ̀n ọjọ́
Ọlọ́run dá ọ Ó sì fi ọ sí àyè tí o wà ní irú àkókò yìí, to love the unlovable, bii àlàáfíà nínú rúkè rúdò, kí o sì fi ayọ̀ tí kò ṣeé dẹ́kun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo. À ti ṣe bẹ́ẹ̀ lè jọ pé kò ṣeéṣẹ, ṣùgbọ́n o le è ṣeé tí o bá kọ́ oun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìmọ̀lára ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àti bí o tilè ṣàkóso wọn. Ètò ẹ̀kọ́ yìí dá lórí àwọn ohun tí a kò kà sí àti nígbà míràn awon ohun ìdojúkọ tí kìí ṣe lásán tí à ń bá pàdé lojojúmọ́, ó sì fún wa ní ìtọ́kasí ẹsẹ̀ Bíbélì láti ṣàkóso ìmọ̀lára wa ní ọ̀nà bíi ti Ọlọ́run.