Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Jer 29:12
ÈRÈDÍ Ìfojú-ìhìnrere wo ìwé Jeremiah
3 Awọn ọjọ
Gbogbo olùpèsè-ọjà ló ní èrèdí fún pípèsè ọjà kọ̀ọ̀kan. Ọlọrun dá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún ètò àti ìlànà pàtàkì kan. Èrèdí ìgbélé-ayé ni kí á rí i dájú pé a gbé ìgbésí ayé wa láti jẹ́ kí èrèdí yìí wá sí ìmúṣẹ. Ẹkọ yìí dù láti wa àwàjinlẹ̀ lórí kókó-ọ̀rọ̀ náà.
Ọgbẹ́ Ọkàn Dé: Ìrètí L'ásìkò Ìsinmi
Ọjọ marun
Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, àkókò ìsinmi jẹ́ àkókò ayọ̀ ńlá...ṣùgbón kíni yío ṣẹlẹ̀ nígbàtí àkókò ìsinmi bá sọ adùn rẹ̀ nù tí ó bá sì di àkókò ìpèníjà látàrí ìbànújẹ́ tàbí àdánù ńlà? Ètò ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí yíó ran àwọn tí ó ń la ìbànújẹ́ kọjá láti ṣàwárí ìtùnù àti ìrètí l'ákòkò ìsinmi, àti láti ṣ'àgbékalẹ̀ àkókò ìsinmi tó n'ítumọ̀ làì fi ti ìbànújẹ́ ọkàn ṣe.
Kí nìdí tí Ọlọrun Fẹràn Mi?
Ọjọ marun
Awọn ibeere: Nigba ti o ba de ọdọ Ọlọrun, gbogbo wa ni wọn. Fun awọn aṣa ti a ti ṣe apejuwe, ọkan ninu awọn ibeere ti ara ẹni ti a le rii ara wa ni, "Kini idi ti Ọlọrun fẹràn mi?" Tabi boya ani, "Bawo ni O ṣe le wa?" Ni opin ètò yii, iwọ yoo ṣe alabapin pẹlu gbogbo awọn ọrọ mimọ mimọ--kọọkan ti o sọ otitọ ti ifẹ ti ailopin ti Ọlọrun fun ọ.
Rin Ìrìn-Àjò Rẹ Láì Sí Ẹrú Wúwo
Ọjọ́ Méje
Ní àkókò pọ̀pọ̀sìnsìn ọ́dún Kérésì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló máa ń fajúro nítorí wàhálà àti àníyàn tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹbí, làálàá ìṣúná, ìpinnu ìdágìrì àti ìjákulẹ̀ nípa àwọn ìrètí wa. Wàyì o, gbé ìgbésẹ. Mí kanlẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ ètò Bíbélì Life.Church yí láti ní òye wípé ẹrù náà tó ń rìn wá mọ́lẹ̀ lè jẹ́ èyí tí Ọlọ́run kò rán wa láti gbé rárá. A ò bá jọ̀wọ́ ẹrù wúwo yìí. Jẹ́ kí a rin ìrìn àjò tó fúyẹ́.
Oswald Chambers: Àlàáfíà - Ìgbésí Ayé nínù Èmí
Ọgbọ̀n ọjọ́
Àlàáfíà: Ìgbésí ayé ninu Èmí je ìṣúra àyọlò ọ̀rọ̀ lábẹ́ ìmísí lati àwon isé Oswald Chambers, akowe ìfọkànsìn to je olùfẹ́ ọ̀wọ́n àgbáyé òònkọ̀wé ati olùkọ̀wé ti Sísa Gbogbo Ipámi Fun Tí Ó Ga Jù Lọ. Ri ìsimi ninu Olórun atipe jèrè óye to jinlé nípa ìjépàtàkì àlàáfíà Olórun ígbésí ayé e.