← Àwon ètò
Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Jer 1:9

Bọ́ Sínú Ìgbésí Ayé Tó Ní Ìtumọ̀
Ọjọ́ márùn-ún
Kí ni kókó ìwàláàyè mi? Kí ni ǹkan tí a dá mi láti gbé ṣe? Kíni ètò Ọlọ́run fún mi? Wọ̀nyí ni àwọn ìbéèrè tí púpọ̀ nínú wa ma ń bèrè nígbà kan tàbí òmíràn ní ìgbésí ayé wa. Ìlépa wa ni láti ṣe ìtúpalẹ̀ ohun tí a nílò láti ṣe fún ipa àti láti ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà. Darapọ̀ mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga ti C3 bí wọ́n ti ń tan ìmọ́lẹ̀ sí kókó náà.

Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run
6 Awọn ọjọ
Ṣe àwárí nínú ìgbésíayé Jeremiah àti Dafidi, pé o kò kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí rẹ, sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí o ní, níbi tí o wà. Kọ́ nipa ohun ìmúrasílẹ̀ fún èrèdí rẹ túmọ̀ sí, bí o ti ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tí yóò bà á jẹ́, kí o sì múra sílẹ̀ láti gbé ìgbésí-ayé onítumọ̀, afògo-fún-Ọlọ́run tí yóò bùkún ayé.