← Àwon ètò
Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Gẹn 2:18
Ìgbéyàwó Gẹ́gẹ́ Bí Ọlọ́run Ṣe Pète Rẹ̀
3 Awọn ọjọ
Yálà ó ti ṣègbéyàwó tàbí o fẹ́ ṣe ìgbéyàwó, ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-mkta yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí ètò rere Ọlọ́run fún ìfarajìn títí-ayé fún ọkọ àti aya. Kọ́ bí a ti ń ṣe àfihàn ìfẹ́ Jesu fún ìyàwó Rẹ̀, ìjọ, nípa ṣíṣe àwàjinlẹ̀ àwọn kókó bí i ìbádọ́rẹ̀ẹ́, ìbímọ, ìjẹ́rìí, ìjẹ́-mímọ́, àti ìgbádùn.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ṣáájú Ìgbéyàwó
Ojọ́ Márùn-ún
Àwọn ìgbéyàwó tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ kìí wáyé fúnra rẹ̀. Ìrètí wa ni wípé o máa ṣàwárí àwọn ìhà, ìlànà àti àṣà tí o nílò láti sọ ìgbéyàwó di èyí tó ní àlàáfíà tó sì nípọn fún gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí ni a fà yọ látinú ìwée Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó Ṣáájú Ìgbéyàwó tí a tọwọ́ọ Nicky àti Sila Lee kọ, àwọn olùkọ̀wé tó kọ Ìwé Ìgbéyàwó Náà.