Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Gẹn 1:28

ÈRÈDÍ Ìfojú-ìhìnrere wo ìwé Jeremiah
3 Awọn ọjọ
Gbogbo olùpèsè-ọjà ló ní èrèdí fún pípèsè ọjà kọ̀ọ̀kan. Ọlọrun dá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún ètò àti ìlànà pàtàkì kan. Èrèdí ìgbélé-ayé ni kí á rí i dájú pé a gbé ìgbésí ayé wa láti jẹ́ kí èrèdí yìí wá sí ìmúṣẹ. Ẹkọ yìí dù láti wa àwàjinlẹ̀ lórí kókó-ọ̀rọ̀ náà.

Ìgbéyàwó Gẹ́gẹ́ Bí Ọlọ́run Ṣe Pète Rẹ̀
3 Awọn ọjọ
Yálà ó ti ṣègbéyàwó tàbí o fẹ́ ṣe ìgbéyàwó, ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-mkta yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí ètò rere Ọlọ́run fún ìfarajìn títí-ayé fún ọkọ àti aya. Kọ́ bí a ti ń ṣe àfihàn ìfẹ́ Jesu fún ìyàwó Rẹ̀, ìjọ, nípa ṣíṣe àwàjinlẹ̀ àwọn kókó bí i ìbádọ́rẹ̀ẹ́, ìbímọ, ìjẹ́rìí, ìjẹ́-mímọ́, àti ìgbádùn.

Níní Ìrírí Ìbádọ́ọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ọjọ́ Márùn-ún
Sé ò n la àkókò aginjù kọjá, láì rí omi tàbí sẹ́lẹ̀rú fún ọkàn rẹ? Báwo ni ìbá ṣe rí tí àsìkò yìí bá ní ìrètí tí ó ga jù lọ: nípasẹ mímọ Ọlọ́run jinlẹ̀, ni ògidì ati tọkàntọkàn? Ètò yìí ń gba'ni ní ìyànjú pé àkọ́kọ̀ yìí kìí ṣe lásán bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ rò pé o kò tẹ̀ sí iwájú. Nítorí pé kò sí ọ̀nà tí ò kò báa rìn, Ọlọ́run n rìn pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bíi Olùtùnú, Afúniníyè & Ọ̀rẹ́.

Bẹrẹ Ọrẹ Kan Pẹlu Jesu
Ọjọ́ méje
Njẹ o bẹrẹ ni igbagbọ titun ninu Jesu Kristi? Ṣe o fẹ lati mọ siwaju sii nipa Kristiẹniti ṣugbọn iwọ ko ni idaniloju ohun-tabi bi o ṣe le beere? Nigbana ni bẹrẹ nibi. Mu lati iwe "Bẹrẹ Nibi" nipasẹ David Dwight ati Nicole Unice.

Ìgbésẹ̀ Mẹ́fà Lọsí Ìdarí Tó Dára jù
Ọjọ́ méje
Ǹjẹ́ o ṣe tán láti dàgbà si gẹ́gẹ́bí olùdarí? Craig Groeschel ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́fà tí a fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú Bíbélì èyí tí ẹnikẹ́ni le tẹ̀lé láti di olùdarí tó dára. Ṣàwárí ìséra-ẹni láti bẹ̀rẹ̀, ìgboyà láti dúró, ẹnìkan tí o lè fún ní ipá, ètò kan tí o lè dá sílẹ̀, ìbárẹ́ titun tí o lè bẹ̀rẹ̀, àti àwọn ewu tí o nílò láti kojú.