Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Gal 5:16

Dídàgbà Nínú Ìfẹ́
Ọjọ́ 5
Ohun tí ó ṣe pàtàkí ní pàtó ní fífẹ́ Ọlọ́run àti fífẹ́ ọmọlàkejì, ṣùgbọ́n báwo ni a ó ṣe ṣe èyí dé ojú àmì? Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé, a kò lè ní ìfẹ́ ẹlòmíràn dunjú nínú agbára ti ara wa. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá gbé ojú s'ókè sí Ọlọ́run tí a rẹ ara wa s'ílẹ̀ ní ìrẹ̀lẹ̀, a lè gbé ayé láti inú ògidì ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ní agbára. Kọ́ síi nípa dídàgbà nínú ìfẹ́ nínú Ètò-ẹ̀kọ́ Bíbélì ọlọ́jọ́-5 láti ọwọ́ Olùṣọ́-àgùntàn Amy Groeschel.

Níní Ìrírí Ìbádọ́ọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ọjọ́ Márùn-ún
Sé ò n la àkókò aginjù kọjá, láì rí omi tàbí sẹ́lẹ̀rú fún ọkàn rẹ? Báwo ni ìbá ṣe rí tí àsìkò yìí bá ní ìrètí tí ó ga jù lọ: nípasẹ mímọ Ọlọ́run jinlẹ̀, ni ògidì ati tọkàntọkàn? Ètò yìí ń gba'ni ní ìyànjú pé àkọ́kọ̀ yìí kìí ṣe lásán bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ rò pé o kò tẹ̀ sí iwájú. Nítorí pé kò sí ọ̀nà tí ò kò báa rìn, Ọlọ́run n rìn pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bíi Olùtùnú, Afúniníyè & Ọ̀rẹ́.

Ìhùwàsí
Ọjọ́ 7
Báwo ní a ṣe lè hu ìwà tí ó yẹ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀? Kí gan-an ni ìwà tí ó yẹ? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-méje yìí wá ìdáhùn jáde nínú ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ Krístì. Jẹ́ kí àwọn ìsítí ojoojúmọ́ yìí, àwọn àṣàrò àdúrà, àti àwọn ésẹ Ìwé-mímọ́ alágbára ṣe ẹ̀dà ọkàn Krístì ní inú rẹ.

Àlàáfíà tó Sonù
Ọjọ́ Méje
N jẹ́ ó ṣeéṣẹ nítòótọ́ láti ní ìrírí àlàáfíà nígbàtí ayé kún fún ìnira? Ìdáhùn kúkúrú ni: Bẹ́ẹni, ṣùgbọ́n kìí ṣe nípa agbára wa. Nínú ọdún tó ti sọ wá di bíi ẹni tí a lù bolẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa la kún fún ìbéèrè. Nínú Ètò Ẹ̀kọ́ Bíbélì olójọ́ méje yìí, tí wọ́n pẹ̀lú àwọn ìwàásù Oníwàásù Craig Groeschel, a ó ṣàwárí bí a ti leè rí àlàáfíà tó sọnù tí gbogbo wa ń pọ̀ùngbẹ.

Jíjẹ Olubori Lori Ògùn Ẹ́ran Àrà
7 Awọn ọjọ
Dídì Atunbi túnmọ̀ sí wiwà sínú ìwà ẹdá títún, eleyii tí a nilo lati mọ ati lati ni òye rẹ. Igbe ayé otun to ni àgbàrá pẹlu idayatọ imudagba lati mọ dènú. Yíó jẹ yiyọ ayọ ìṣẹgun aitọ jọ lori ẹṣẹ nigba tí a di atunbi laiti ni ijinlẹ oyè nínú "rìnrìn pẹlú Ọlọrun" èyí ni yíò jẹ irin àjò wá fún ọjọ́ méje yi, dé amure ijókó rẹ dáadáa.

Kíni Ìfẹ́ Tòótọ́?
Ojo Méjìlá
Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ mọ̀ ohun ti ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Sùgbọ́n ènìyàn péréte ló màá ń wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́. Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn àkòrí inú Bíbélì àti ìsúra tó ṣe pàtàkí jùlọ ní ìgbé-ayé Krìstìẹ́nì. Ẹ̀kọ́ yìí làti Ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend ṣe àgbéyẹ̀wò ìtumọ̀ ìfẹ́ ní ìlànà Bíbélì àti bí a ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn.