Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Gal 2:20

Òpin Ìgbéra-à-miga Látọwọ́ Kyle Idleman
Ọjọ́ Méje
A fa ètò yí yọ látinú iṣẹ́ àkànṣe tó tẹ̀lé ìwé Kyle Idle "Not A Fan," a pè ọ́ láti wá pa ìgbéraga tì, nítorí lẹ́yìn èyí ni o lè tẹ̀lé ìlànà àtinúdá ti Jésù.

Gbígbé Ìgbésí Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Bíbá Ọlọ́run Pàdé
Ọjọ́ Méje
Ohun tí ó jẹ́ gbòógì ní ayé yìí ni láti yan ohun kan: taani tàbí kíni a óò gbé ìgbésí ayé wa lé lórí? Ohun tí a yàn yí á mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe àwọn ìpinnu tí yíó tọ́ka irú ẹni tí a ó jẹ́, bí nǹkan ṣe ń rí ní ara wa, àwọn ẹni tàbí ohun tí a kà sí pàtàkì àti àwọn ohun tí a ó ti gbéṣe níkẹyìn ọjọ́ wa. Tí a bá fi ara wa nìkan ṣoo ṣe kókó tàbí àwọn ohun ti ayé yìí kò ní í da ohunkóhun fún wa ju ìparun lọ.

Ṣíṣe Àwàrí Òtítọ́ Ọlọ́run Nínú Ìjì Ayé
Ọjọ́ 10
Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò bọ́ lọ́wọ́ wàhálà nínú ayé yìí. Ìwé Jòhánù 16:33 ṣe ìlérí wípé wọn yíó wà. Tí o bá ń dojúkọ àwọn ìjì ayé ní báyìí, ètò-ìfọkànsìn yìí wà fún ọ. Ó jẹ́ ìránnilétí ìrètí tí ń mú wa la ìjì líle nínú ìgbésí ayé já. Àti pé tí o kò bá dojúkọ àwọn ìjì kankan ní àkókò yìi, yíó fún ọ ní ìpìlẹ̀ tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti la àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú kọjá.